Luke 9:28-36

Ìràpadà

28 a bÓ sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. 29Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, 30 cSì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀: 31Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. 32 dṢùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró. 33 eÓ sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí: jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta; ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)

34Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó ṣíji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ. 35 fOhùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” 36 gNígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.

Copyright information for YorBMYO